Eedi ree, ọlọkada yii gun ẹni to n la wọn nija pa

Awọn agba bọ, wọn ni olulaja lo n gba ọgbẹ, bẹẹ gan-an lo ri fun baale ile kan, Oloogbe Yusuf Akodo, ti wọn gun pa lasiko to n laja to waye laarin awọn eeyan meji niluu Eko laipẹ yii.

A gbọ pe loju ọna marosẹ Igbira Road, niluu Idi-Araba, niṣẹlẹ ọhun ti waye ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja ogun iṣẹju laṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii. Wọn ni lọjọ yii ni oloogbe naa to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ eleto alaabo kan niluu Eko pade iku ojiji lasiko to n laja to bẹ silẹ laarin ọlọkada kan ati ero to gbe. Ẹnu ibi to ti n laja naa lo wa ti ọlọkada to n ba ero rẹ ja fi yọ ọbẹ aṣooro kan jade, bo ṣe ni k’oun gbe e le ẹni to n ba a ja bayii, oloogbe lo fara gba a, ẹgbẹ ikun si ni ọbẹ naa ti gun un. Igbe to fi bọ’nu lo jẹ kawọn eeyan to wa nitosi mọ pe nnkan buruku ti ṣe e, bẹẹ lo mudii lọ silẹ, to si n japoro iku. Ṣe lọrọ di bo o lọ o yago fun mi lọjọ naa.

Loju-ẹsẹ ni ọlọkada ọhun ti sa lọ, nigba to ri i pe ẹni t’oun gun ti ku. Wọn gbe olulaja naa lọ sileewosan ijọba ‘Lagos State University Teaching Hospital’, to wa lagbegbe Idi-Araba, fun itọju, ṣugbọn awọn dokita sọ pe ọkunrin naa ti ku ki wọn too gbe e de ileewosan awọn.

Eedi ree, ọlọkada yii gun ẹni to n la wọn nija pa
Eedi ree, ọlọkada yii gun ẹni to n la wọn nija pa

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, sọ pe awọn araalu kan tiṣẹle ọhun ṣoju wọn ni wọn ranṣẹ pe ọlọpaa agbegbe naa. Loju-ẹsẹ tawọn ọlọpaa gbọ si iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti lọ sibẹ, wọn ba oloogbe naa nilẹ nibi to ṣubu si ninu agbara ẹjẹ, wọn gbe e lọ sileewosan ijọba kan to wa lagbegbe Idi-Araba, nitosi ibi ti iṣẹle ohun ti waye. Awon dọkita ko gba a lọwọ wọn. Wọn ni oku rẹ ni wọn gbe wa.

Alukoro ni awọn n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu bayii lati fọwọ ofin mu ọlọkada to gun oloogbe naa pa, tawọn si maa foju rẹ bale-ẹjọ lẹyin tawọn ba pari iwadii awọn nipa rẹ.


Be the first to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published.