Ẹgbẹ PDP Ekiti Se Ikilọ fun Fayọṣe, wọn lo tun fẹẹ ta ẹgbẹ awọn fun Oyebanji

Ẹgbẹ PDP Ekiti Se Ikilọ fun Fayọṣe, wọn lo tun fẹẹ ta ẹgbẹ awọn fun Oyebanji
Ẹgbẹ PDP Ekiti Se Ikilọ fun Fayọṣe, wọn lo tun fẹẹ ta ẹgbẹ awọn fun Oyebanji

Ẹgbẹ Alaburada ipinlẹ Ekiti, ti ṣekilọ to nipọn fun gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Ọgbẹni Ayọ Fayọṣe, pe ko jinna sibi ipade apapọ (National Congress) ẹgbẹ naa to n bọ ninu oṣu Kẹjọ, ọdun ta a wa yii.

Bakan naa ni ẹgbẹ naa tun fẹsun kan gomina tẹlẹri ọhun pe o tun fẹẹ pada ta ẹgbẹ ọhun fun Gomina ipinlẹ ọhun, Ọgbẹni Biọdun Oyebanji, gẹgẹ bo ṣe ta a lọdun 2022, lakooko idibo gomina to waye nigba naa.

Ikilọ yii lo waye lakooko ti gomina tẹlẹri ọhun ṣabẹwo sijọba ibilẹ Isẹ/Ọrun. Abẹwo yii waye gẹgẹ bii igbesẹ ati ipolongo fun eto ipade gbogboo ẹgbẹ PDP to n bọ lọna.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Ọgbẹni Ayọ Fayọṣe ti bẹrẹ eto abẹwo ati ifikunlukun ka gbogbo ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Ekiti, lati le la awọn ọmọ ẹgbẹ naa lọyẹ nipa eto ipade apapọ naa.

Alaga ẹgbẹ naa nijọba ibilẹ Isẹ/Ọrun, Ọgbẹni Ojo Sunday, atawọn ọmọ ẹgbẹ naa nijọba ibilẹ ọhun. Ikilọ yii lo ni o ṣe pataki lati le jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Ekiti le fura, ki wọn ma ṣe jẹ ki gomina tẹlẹri yii tan wọn jẹ.

Awọn ẹgbẹ naa ninu iwe kan ti wọn fọwọ si ti wọn fi ṣọwọ si awọn oniroyin l’Ado-Ekiti, sọ pe ohun ti gomina tẹlẹri ninu ẹgbẹ PDP yii ko ye awọn, nitori laipẹ yii lawọn deede ri i nigba kan ninu fidio kan to gba gbogbo ori afẹfẹ kan, nibi to ti fọwọ si i pe ki Gomina Oyebanji maa tẹsiwaju si i ninu iṣejọba rẹ, ati pe ko pada dije fun saa keji.

Igbesẹ yii ni wọn juwe pe o lodi sofin ẹgbẹ Alaburada nipinlẹ naa.

‘‘A tun fẹẹ fihan pe gbogbo awọn alatilẹyin Ọgbẹn Ayọ Fayọṣe ni ko kopa ninu gbogbo eto ati igbesẹ ti ẹgbẹ PDP n ṣe nipinlẹ Ekiti lati le ji ẹgbẹ naa pada, ati lati le gba ìjọba pada lọwọ ẹgbẹ Onigbalẹ nipinlẹ naa.”

Ninu iwe naa ni wọn tun ṣalaye pe awọn ko mọ boya ẹgbẹ PDP tabi ẹgbẹ APC lo wa, pẹlu bi ko ṣe yọju si gbogbo eto ti wọn n ṣe lati ṣe iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP gbogbo nipinlẹ Ekiti.

Wọn sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo awọn pẹlu bawọn ṣe ṣadeede ri gomina tẹlẹri ọhun ni awọn ijọba ibilẹ kan, nibi to ti n ṣe ipolongo ati ifikunluku pe ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ekiti ko gbọdọ ku.

“Gbogbo awa ọmọ ẹgbẹ Alaburada ipinlẹ Ekiti lo jẹ oniwatutu ti a si bọwọ fun ofin ẹgbẹ wa, ti a si n gbe pọ pẹlu alaafia. Gbogbo agbara ni a n sa lati ri i pe ẹgbẹ wa ni itẹsiwaju, ati pe a gbajọba pada lọwọ ẹgbẹ APC ninu eto idibo gomina to n bọ lọjọ iwaju.

“A ti ṣetan lati ri i pe a dena gbogbo ọgbọn ti gomina ana, Ayọ Fayoṣe, le ta lati tan ẹgbẹ naa jẹ gẹgẹ bo ṣe maa n tan an jẹtẹlẹ, ti yoo lọọ gba owo lọwọ ẹgbẹ oṣelu miiran, ti yoo si gbabọde fun ẹgbẹ tiẹ.”

Ninu iwe naa, wọn rọ alaga ẹgbẹ PDP l’Ekiti, Ẹnjinnia Alaba Agboọla ati awọn oloye inu ẹgbẹ naa ki wọn ma ṣe kawọ gbera lati maa wo Ọgbẹni Ayọ Fayọṣe niran pẹlu bo ṣe fẹẹ tun ta ẹgbẹ naa nigba keji.


Be the first to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published.